Oyè ológun ni oyè Ajagunnà. Àwọn ọdẹ àgbáyé, tí olórìí wọn ń jẹ́ Kábíèsì Oṣògún, ni ó má a ń yàn ẹni tí Ọọ̀ni ó fi jẹ oyè Ajagunnà.
Tí àwọn ọmọ ilẹ̀ káàárọ̀-o-ò-jíire ní àpapọ̀ bá fẹ́ ja ogun, Ajagunnà ni jagunjagun tí yó ṣe olóri ogun. Ó ti lé ni igba ọdún tí àwà Yorùbá ti para pọ̀ láti já ogun pẹ̀lú àwọ́n mìíràn. Ẹ ó rántí pé láti bíi 1774 títí di 1880, ara wa ni à ń bá jà! Ògun Ìjàyè, Ogun Kírìjì, Ogun Jálumi, Ogun Èkìtì Parapọ̀, àti bẹ́ẹ lọ, àwà Yorùbá ni à ń bá ara wa jà.
Nítorí rògbòdìyàn àwọn Fúlàní darandaran tí o gbòde báyìí, ogun àpapọ̀ ti dé odè o! Ìdí tí oyè Ajagunnà fi ṣe pàtàkì nísiìí nì yẹn o.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé oyè Ògún àti ogun ni oyè yìí, Òrìṣà funfun kán wà tí à ń pè ní “Ajagunnà.” Òrìṣà funfun yìí jẹ mọ́ Ọbàtálá. Òrìṣà Ajagunnà ni a gbọ́dọ̀ bọ tí a bá ń lọ si ojú ogun.